25 Ṣugbọn bi ọkunrin na ba ri ọmọbinrin ti afẹsọna na ni igbẹ́, ti ọkunrin na si fi agbara mú u, ti o si bà a dàpọ; njẹ kìki ọkunrin na ti o bá a dàpọ ni ki o kú:
26 Ṣugbọn si ọmọbinrin na ni ki iwọ ki o máṣe ohun kan; ẹ̀ṣẹ ti o yẹ si ikú kò sí lara ọmọbinrin na: nitori bi igbati ọkunrin kan dide si ẹnikeji rẹ̀, ti o si pa a, bẹ̃li ọ̀ran yi ri:
27 Nitoripe o bá a ninu igbẹ́; ọmọbinrin na ti afẹsọna kigbe, kò si sí ẹniti yio gbà a silẹ.
28 Bi ọkunrin kan ba si ri ọmọbinrin kan ti iṣe wundia, ti a kò ti fẹsọna fun ọkọ, ti o si mú u, ti o si bá a dàpọ, ti a si mú wọn;
29 Njẹ ki ọkunrin na ti o bá a dàpọ ki o fi ãdọta ṣekeli fadakà fun baba ọmọbinrin na, ki on ki o si ma ṣe aya rẹ̀, nitoriti o ti tẹ́ ẹ logo, ki on ki o máṣe kọ̀ ọ silẹ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo.
30 Ki ọkunrin kan ki o máṣe fẹ́ aya baba rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe tú aṣọ baba rẹ̀.