27 Nitoripe o bá a ninu igbẹ́; ọmọbinrin na ti afẹsọna kigbe, kò si sí ẹniti yio gbà a silẹ.
28 Bi ọkunrin kan ba si ri ọmọbinrin kan ti iṣe wundia, ti a kò ti fẹsọna fun ọkọ, ti o si mú u, ti o si bá a dàpọ, ti a si mú wọn;
29 Njẹ ki ọkunrin na ti o bá a dàpọ ki o fi ãdọta ṣekeli fadakà fun baba ọmọbinrin na, ki on ki o si ma ṣe aya rẹ̀, nitoriti o ti tẹ́ ẹ logo, ki on ki o máṣe kọ̀ ọ silẹ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo.
30 Ki ọkunrin kan ki o máṣe fẹ́ aya baba rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe tú aṣọ baba rẹ̀.