12 Ki iwọ ki o ní ibi kan pẹlu lẹhin ibudó, nibiti iwọ o ma jade lọ si:
13 Ki iwọ ki o si ní ìwalẹ kan pẹlu ohun-ìja rẹ; yio si ṣe, nigbati iwọ o ba gbọnsẹ lẹhin ibudó, ki iwọ ki o fi wàlẹ, ki iwọ ki o si yipada, ki o bò ohun ti o ti ara rẹ jade:
14 Nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ nrìn lãrin ibudó rẹ, lati gbà ọ, ati lati fi awọn ọtá rẹ fun ọ; nitorina ki ibudó rẹ ki o jẹ́ mimọ́: ki on ki o máṣe ri ohun aimọ́ kan lọdọ rẹ, on a si pada lẹhin rẹ.
15 Iwọ kò gbọdọ fà ẹrú ti o sá lati ọdọ oluwa rẹ̀ tọ̀ ọ wá lé oluwa rẹ̀ lọwọ:
16 Ki on ki o bá ọ joko, ani lãrin nyin, ni ibi ti on o yàn ninu ọkan ni ibode rẹ, ti o wù u jù: ki iwọ ki o máṣe ni i lara.
17 Ki àgbere ki o máṣe sí ninu awọn ọmọbinrin Israeli, tabi oníwà-sodomu ninu awọn ọmọkunrin Israeli.
18 Iwọ kò gbọdọ mú owo ọ̀ya àgbere, tabi owo ajá, wá sinu ile OLUWA Ọlọrun rẹ fun ẹjẹ́kẹjẹ: nitoripe irira ni, ani awọn mejeji si OLUWA Ọlọrun rẹ.