1 BI ọkunrin kan ba fẹ́ obinrin kan, ti o si gbé e niyawo, yio si ṣe, bi obinrin na kò ba ri ojurere li oju ọkunrin na, nitoriti o ri ohun alebù kan lara rẹ̀: njẹ ki o kọ iwé ikọsilẹ fun obinrin na, ki o fi i lé e lọwọ, ki o si rán a jade kuro ninu ile rẹ̀.
2 Nigbati on ba si jade kuro ninu ile rẹ̀, on le lọ, ki o ma ṣe aya ọkunrin miran.
3 Bi ọkọ rẹ̀ ikẹhin ba si korira rẹ̀, ti o si kọ iwé ikọsilẹ fun u, ti o si fi i lé e lọwọ, ti o si rán a jade kuro ninu ile rẹ̀; tabi bi ọkọ ikẹhin ti o fẹ́ ẹ li aya ba kú;
4 Ọkọ rẹ̀ iṣaju, ti o rán a jade kuro, ki o máṣe tun ní i li aya lẹhin ìgba ti o ti di ẹni-ibàjẹ́ tán; nitoripe irira ni niwaju OLUWA: iwọ kò si gbọdọ mu ilẹ na ṣẹ̀, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní.
5 Bi ọkunrin kan ba gbé iyawo titun, ki o máṣe lọ si ogun, bẹ̃ni ki a máṣe fun u ni iṣẹkiṣẹ kan ṣe: ki o ri àye ni ile li ọdún kan, ki o le ma mu inu aya rẹ̀ ti o ní dùn.
6 Ẹnikan kò gbọdọ gbà iya-ọ̀lọ tabi ọmọ-ọlọ ni ògo: nitoripe ẹmi enia li o gbà li ògo nì.
7 Bi a ba mú ọkunrin kan ti njí ẹnikan ninu awọn arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ Israeli, ti o nsìn i bi ẹrú, tabi ti o tà a; njẹ olè na o kú; bẹ̃ni iwọ o mú ìwabuburu kuro lãrin nyin.