13 Bi o ti wù ki o ri iwọ kò gbọdọ má mú ògo rẹ̀ pada fun u, nigbati õrùn ba nwọ̀, ki on ki o le ri aṣọ bora sùn, ki o si sure fun ọ: ododo ni yio si jasi fun ọ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ.
14 Iwọ kò gbọdọ ni alagbaṣe kan lara ti iṣe talakà ati alaini, ibaṣe ninu awọn arakunrin rẹ, tabi ninu awọn alejò rẹ ti mbẹ ni ilẹ rẹ ninu ibode rẹ:
15 Ni ọjọ́ rẹ̀, ni ki iwọ ki o sanwo ọ̀ya rẹ̀ fun u, bẹ̃ni ki o máṣe jẹ ki õrùn ki o wọ̀ bá a; nitoripe talakà li on, o si gbẹkẹ rẹ̀ lé e: ki o má ba kepè OLUWA si ọ, a si di ẹ̀ṣẹ si ọ lọrùn.
16 A kò gbọdọ pa awọn baba nitori ẹ̀ṣẹ awọn ọmọ, bẹ̃ni a kò gbọdọ pa awọn ọmọ nitori awọn baba: olukuluku enia li a o pa nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
17 Iwọ kò gbọdọ yi idajọ alejò po, tabi ti alainibaba; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe gbà aṣọ opó ni ogò:
18 Ṣugbọn ki iwọ ki o ranti pe iwọ ti ṣe ẹrú ni Egipti, OLUWA Ọlọrun rẹ si gbà ọ silẹ kuro nibẹ̀: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ lati ma ṣe nkan yi.
19 Nigbati iwọ ba kore rẹ li oko rẹ, ti iwọ ba si gbagbé ití-ọkà kan silẹ ninu oko, ki iwọ ki o máṣe pada lọ mú u: ki o le ma jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó: ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le ma busi i fun ọ, ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo.