4 Ọkọ rẹ̀ iṣaju, ti o rán a jade kuro, ki o máṣe tun ní i li aya lẹhin ìgba ti o ti di ẹni-ibàjẹ́ tán; nitoripe irira ni niwaju OLUWA: iwọ kò si gbọdọ mu ilẹ na ṣẹ̀, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní.
5 Bi ọkunrin kan ba gbé iyawo titun, ki o máṣe lọ si ogun, bẹ̃ni ki a máṣe fun u ni iṣẹkiṣẹ kan ṣe: ki o ri àye ni ile li ọdún kan, ki o le ma mu inu aya rẹ̀ ti o ní dùn.
6 Ẹnikan kò gbọdọ gbà iya-ọ̀lọ tabi ọmọ-ọlọ ni ògo: nitoripe ẹmi enia li o gbà li ògo nì.
7 Bi a ba mú ọkunrin kan ti njí ẹnikan ninu awọn arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ Israeli, ti o nsìn i bi ẹrú, tabi ti o tà a; njẹ olè na o kú; bẹ̃ni iwọ o mú ìwabuburu kuro lãrin nyin.
8 Ma kiyesi àrun-ẹ̀tẹ, ki iwọ ki o ṣọra gidigidi ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti awọn alufa awọn ọmọ Lefi yio ma kọ́ nyin: bi emi ti pa a laṣẹ fun wọn, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o ma kiyesi lati ṣe.
9 Ranti ohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe si Miriamu li ọ̀na, nigbati ẹnyin ti Egipti jade wá.
10 Nigbati iwọ ba wín arakunrin rẹ li ohun kan, ki iwọ ki o máṣe lọ si ile rẹ̀ lati mú ògo rẹ̀ wá.