6 Ẹnikan kò gbọdọ gbà iya-ọ̀lọ tabi ọmọ-ọlọ ni ògo: nitoripe ẹmi enia li o gbà li ògo nì.
7 Bi a ba mú ọkunrin kan ti njí ẹnikan ninu awọn arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ Israeli, ti o nsìn i bi ẹrú, tabi ti o tà a; njẹ olè na o kú; bẹ̃ni iwọ o mú ìwabuburu kuro lãrin nyin.
8 Ma kiyesi àrun-ẹ̀tẹ, ki iwọ ki o ṣọra gidigidi ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti awọn alufa awọn ọmọ Lefi yio ma kọ́ nyin: bi emi ti pa a laṣẹ fun wọn, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o ma kiyesi lati ṣe.
9 Ranti ohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe si Miriamu li ọ̀na, nigbati ẹnyin ti Egipti jade wá.
10 Nigbati iwọ ba wín arakunrin rẹ li ohun kan, ki iwọ ki o máṣe lọ si ile rẹ̀ lati mú ògo rẹ̀ wá.
11 Ki iwọ ki o duro lode gbangba, ki ọkunrin na ti iwọ wín ni nkan, ki o mú ògo rẹ̀ jade tọ̀ ọ wá.
12 Bi ọkunrin na ba si ṣe talakà, ki iwọ ki o máṣe sùn ti iwọ ti ògo rẹ̀.