7 Bi ọkunrin na kò ba si fẹ́ lati mú aya arakunrin rẹ̀, njẹ ki aya arakunrin rẹ̀ ki o gòke lọ si ẹnubode tọ̀ awọn àgba lọ, ki o si wipe, Arakunrin ọkọ mi kọ̀ lati gbé orukọ arakunrin rẹ̀ ró ni Israeli, on kò fẹ́ ṣe iṣẹ arakunrin ọkọ mi.
8 Nigbana ni awọn àgba ilu rẹ̀ yio pè e, nwọn a si sọ fun u: bi o ba si duro si i, ti o si wipe, Emi kò fẹ́ lati mú u;
9 Nigbana ni aya arakunrin rẹ̀ yio tọ̀ ọ wá niwaju awọn àgba na, on a si tú bàta rẹ̀ kuro li ẹsẹ̀ rẹ̀, a si tutọ si i li oju; a si dahùn, a si wipe, Bayi ni ki a ma ṣe si ọkunrin na ti kò fẹ́ ró ile arakunrin rẹ̀.
10 A o si ma pè orukọ rẹ̀ ni Israeli pe, Ile ẹniti a tú bàta rẹ̀.
11 Bi awọn ọkunrin ba mbá ara wọn jà, ti aya ọkan ba si sunmọtosi lati gbà ọkọ rẹ̀ lọwọ ẹniti o kọlù u, ti on si nawọ́ rẹ̀, ti o si di i mú li abẹ:
12 Nigbana ni ki iwọ ki o ke ọwọ́ rẹ̀ kuro, ki oju rẹ ki o máṣe ṣãnu fun u.
13 Iwọ kò gbọdọ ní onirũru ìwọn ninu àpo rẹ, nla ati kekere.