12 Awọn wọnyi ni ki o duro lori òke Gerisimu, lati ma sure fun awọn enia na, nigbati ẹnyin ba gòke Jordani; Simeoni, ati Lefi, ati Juda, ati Issakari, ati Josefu, ati Benjamini:
13 Awọn wọnyi ni yio si duro lori òke Ebali lati gegún; Reubeni, Gadi, ati Aṣeri, ati Sebuluni, Dani, ati Naftali.
14 Awọn ọmọ Lefi yio si dahùn, nwọn o si wi fun gbogbo awọn ọkunrin Israeli li ohùn rara pe,
15 Egún ni fun ọkunrin na ti o yá ere gbigbẹ́ tabi didà, irira si OLUWA, iṣẹ ọwọ́ oniṣọnà, ti o si gbé e kalẹ ni ìkọ̀kọ̀. Gbogbo enia yio si dahùn wipe, Amin.
16 Egún ni fun ẹniti kò fi baba rẹ̀ tabi iya rẹ̀ pè. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
17 Egún ni fun ẹniti o ṣí àla ẹnikeji rẹ̀ kuro. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
18 Egún ni fun ẹniti o ṣì afọju li ọ̀na. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.