2 Yio si ṣe li ọjọ́ ti ẹnyin ba gòke Jordani lọ si ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o si kó okuta nla jọ, ki iwọ ki o si fi ẹfun rẹ́ wọn.
3 Ki iwọ ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi sara wọn, nigbati iwọ ba rekọja; ki iwọ ki o le wọ̀ inu ilẹ na lọ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin, bi OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ, ti ṣe ileri fun ọ.
4 Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba gòke Jordani tán, ẹnyin o kó okuta wọnyi jọ, ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, li òke Ebali, ki iwọ ki o si fi ẹfun rẹ́ wọn.
5 Nibẹ̀ ni ki iwọ ki o si mọ pẹpẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ, pẹpẹ okuta kan: iwọ kò gbọdọ fi ohun-èlo irin kàn wọn.
6 Okuta aigbẹ́ ni ki iwọ ki o fi mọ pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ: ki iwọ ki o si ma ru ẹbọ sisun lori rẹ̀ si OLUWA Ọlọrun rẹ:
7 Ki iwọ ki o si ma ru ẹbọ alafia, ki iwọ ki o si jẹun nibẹ̀; ki iwọ ki o ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ.
8 Ki iwọ ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi sara okuta wọnyi, ki o hàn gbangba.