21 OLUWA yio si mu ajakalẹ-àrun lẹ̀ mọ́ ọ, titi on o fi run ọ kuro lori ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a.
22 OLUWA yio si fi àrun-igbẹ kọlù ọ, ati ibà, ati igbona, ati ijoni nla, ati idà, ati ìrẹdanu, ati imuwodu; nwọn o si lepa rẹ titi iwọ o fi run.
23 Ọrun rẹ ti mbẹ lori rẹ yio jẹ́ idẹ, ilẹ ti mbẹ nisalẹ rẹ yio si jẹ́ irin.
24 OLUWA yio sọ òjo ilẹ rẹ di ẹ̀tù ati ekuru: lati ọrun ni yio ti ma sọkalẹ si ọ, titi iwọ o fi run.
25 OLUWA yio si mu ọ di ẹni ikọlù niwaju awọn ọtá rẹ: iwọ o jade tọ̀ wọn lọ li ọ̀na kan, iwọ o si sá niwaju wọn li ọ̀na meje: a o si ṣí ọ kiri gbogbo ijọba aiye.
26 Okú rẹ yio si jẹ́ onjẹ fun gbogbo ẹiyẹ oju-ọ̀run, ati fun ẹranko aiye, kò si sí ẹniti yio lé wọn kuro.
27 OLUWA yio si fi õwo Egipti lù ọ, ati iyọdi, ati ekúru, ati ẹyi-ara, eyiti a ki yio le wòsan.