25 OLUWA yio si mu ọ di ẹni ikọlù niwaju awọn ọtá rẹ: iwọ o jade tọ̀ wọn lọ li ọ̀na kan, iwọ o si sá niwaju wọn li ọ̀na meje: a o si ṣí ọ kiri gbogbo ijọba aiye.
26 Okú rẹ yio si jẹ́ onjẹ fun gbogbo ẹiyẹ oju-ọ̀run, ati fun ẹranko aiye, kò si sí ẹniti yio lé wọn kuro.
27 OLUWA yio si fi õwo Egipti lù ọ, ati iyọdi, ati ekúru, ati ẹyi-ara, eyiti a ki yio le wòsan.
28 OLUWA yio fi isinwin kọlù ọ, ati ifọju, ati ipàiya:
29 Iwọ o si ma fi ọwọ́ talẹ li ọsán gangan, bi afọju ti ifi ọwọ́ talẹ ninu òkunkun, iwọ ki yio si ri rere ninu ọ̀na rẹ: ẹni inilara ṣá ati ẹni kikó li ọjọ́ gbogbo ni iwọ o jẹ́, ki o si sí ẹniti o gbà ọ.
30 Iwọ o fẹ́ iyawo, ọkunrin miran ni yio si bá a dàpọ: iwọ o kọ ile, iwọ ki yio si gbé inu rẹ̀: iwọ o gbìn ọgbà-àjara, iwọ ki yio si ká eso rẹ̀.
31 A o si pa akọmalu rẹ li oju rẹ, iwọ ki yio si jẹ ninu rẹ̀: kẹtẹkẹtẹ rẹ li a o si fi agbara mú lọ kuro li oju rẹ, a ki yio si mú u pada fun ọ wá: a o fi agutan rẹ fun awọn ọtá rẹ, iwọ ki yio si lí ẹniti yio gbà ọ.