46 Nwọn o si wà lori rẹ fun àmi ati fun iyanu, ati lori irú-ọmọ rẹ lailai:
47 Nitoriti iwọ kò fi àyọ sìn OLUWA Ọlọrun rẹ, ati inudidun, nitori ọ̀pọ ohun gbogbo:
48 Nitorina ni iwọ o ṣe ma sìn awọn ọtá rẹ ti OLUWA yio rán si ọ, ninu ebi, ati ninu ongbẹ, ati ninu ìhoho, ati ninu ainí ohun gbogbo: on o si fi àjaga irin bọ̀ ọ li ọrùn, titi yio fi run ọ.
49 OLUWA yio gbé orilẹ-ède kan dide si ọ lati ọ̀na jijìn, lati opin ilẹ wa bi idì ti ifò; orilẹ-ède ti iwọ ki yio gbọ́ ède rẹ̀;
50 Orilẹ-ède ọdaju, ti ki yio ṣe ojuṣaju arugbo, ti ki yio si ṣe ojurere fun ewe:
51 On o si ma jẹ irú ohunọ̀sin rẹ, ati eso ilẹ rẹ, titi iwọ o fi run: ti ki yio kù ọkà, ọti-waini, tabi oróro, tabi ibisi malu rẹ, tabi ọmọ agutan silẹ fun ọ, titi on o fi run ọ.
52 On o si dótì ọ ni ibode rẹ gbogbo, titi odi rẹ ti o ga ti o si le yio fi wó lulẹ, eyiti iwọ gbẹkẹle, ni ilẹ rẹ gbogbo: on o si dótì ọ ni ibode rẹ gbogbo, ni gbogbo ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti fi fun ọ.