49 OLUWA yio gbé orilẹ-ède kan dide si ọ lati ọ̀na jijìn, lati opin ilẹ wa bi idì ti ifò; orilẹ-ède ti iwọ ki yio gbọ́ ède rẹ̀;
50 Orilẹ-ède ọdaju, ti ki yio ṣe ojuṣaju arugbo, ti ki yio si ṣe ojurere fun ewe:
51 On o si ma jẹ irú ohunọ̀sin rẹ, ati eso ilẹ rẹ, titi iwọ o fi run: ti ki yio kù ọkà, ọti-waini, tabi oróro, tabi ibisi malu rẹ, tabi ọmọ agutan silẹ fun ọ, titi on o fi run ọ.
52 On o si dótì ọ ni ibode rẹ gbogbo, titi odi rẹ ti o ga ti o si le yio fi wó lulẹ, eyiti iwọ gbẹkẹle, ni ilẹ rẹ gbogbo: on o si dótì ọ ni ibode rẹ gbogbo, ni gbogbo ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti fi fun ọ.
53 Iwọ o si jẹ ọmọ inu rẹ, ẹran ara awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati ti awọn ọmọ rẹ obinrin ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ; ninu idótì na ati ninu ihámọ na ti awọn ọtá rẹ yio há ọ mọ́.
54 Ọkunrin ti àwọ rẹ̀ tutù ninu nyin, ti o si ṣe ẹlẹgẹ, oju rẹ̀ yio korò si arakunrin rẹ̀, ati si aya õkanàiya rẹ̀, ati si iyokù ọmọ rẹ̀ ti on jẹ kù:
55 Tobẹ̃ ti on ki yio bùn ẹnikan ninu wọn, ninu ẹran awọn ọmọ ara rẹ̀ ti o jẹ, nitoriti kò sí ohun kan ti yio kù silẹ fun u ninu idótì na ati ninu ihámọ, ti awọn ọtá rẹ yio há ọ mọ́ ni ibode rẹ gbogbo.