61 Gbogbo àrun pẹlu, ati gbogbo iyọnu, ti a kò kọ sinu iwé ofin yi, awọn ni OLUWA yio múwa bá ọ, titi iwọ o fi run.
62 Diẹ li ẹnyin o si kù ni iye, ẹnyin ti ẹ ti dabi irawọ oju-ọrun ni ọ̀pọlọpọ: nitoriti iwọ kò gbà ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́.
63 Yio si ṣe, bi OLUWA ti yọ̀ sori nyin lati ṣe nyin ni ire, ati lati sọ nyin di pupọ̀; bẹ̃ni OLUWA yio si yọ̀ si nyin lori lati run nyin, ati lati pa nyin run; a o si fà nyin tu kuro lori ilẹ na ni ibi ti iwọ nlọ lati gbà a.
64 OLUWA yio si tu ọ ká sinu enia gbogbo, lati opin ilẹ dé opin ilẹ; nibẹ̀ ni iwọ o si ma bọ oriṣa ti iwọ ati baba rẹ kò mọ̀ rí, ani igi ati okuta.
65 Ati lãrin orilẹ-ède wọnyi ni iwọ ki yio ri irọrun, bẹ̃li atẹlẹsẹ̀ rẹ ki yio ri isimi: ṣugbọn OLUWA yio fi iwarìri àiya, ati oju jijoro, ati ibinujẹ ọkàn fun ọ:
66 Ẹmi rẹ yio sọrọ̀ ni iyemeji li oju rẹ; iwọ o si ma bẹ̀ru li oru ati li ọsán, iwọ ki yio si ní idaniloju ẹmi rẹ.
67 Li owurọ̀ iwọ o wipe, Alẹ iba jẹ́ lẹ! ati li alẹ iwọ o wipe, Ilẹ iba jẹ́ mọ́! nitori ibẹ̀ru àiya rẹ ti iwọ o ma bẹ̀ru, ati nitori iran oju rẹ ti iwọ o ma ri.