11 Awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, awọn aya nyin, ati alejò rẹ, ti mbẹ lãrin ibudó rẹ, lati aṣẹgi rẹ dé apọnmi rẹ:
12 Ki iwọ ki o le wọ̀ inu majẹmu OLUWA Ọlọrun rẹ, ati ibura rẹ̀, ti OLUWA Ọlọrun rẹ bá ọ ṣe li oni:
13 Ki o le fi idi rẹ kalẹ li oni li enia kan fun ara rẹ̀, ati ki on ki o le ma ṣe Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ fun ọ, ati bi o ti bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu.
14 Ki si iṣe ẹnyin nikan ni mo bá ṣe majẹmu yi ati ibura yi;
15 Ṣugbọn ẹniti o bá wa duro nihin li oni niwaju OLUWA Ọlọrun wa, ẹniti kò sí nihin pẹlu wa li oni:
16 (Nitoripe ẹnyin mọ̀ bi awa ti gbé ilẹ Egipti; ati bi awa ti kọja lãrin orilẹ-ède ti ẹnyin là kọja;
17 Ẹnyin si ti ri ohun irira wọn, ati ere wọn, igi ati okuta, fadakà ati wurà, ti o wà lãrin wọn.)