16 (Nitoripe ẹnyin mọ̀ bi awa ti gbé ilẹ Egipti; ati bi awa ti kọja lãrin orilẹ-ède ti ẹnyin là kọja;
17 Ẹnyin si ti ri ohun irira wọn, ati ere wọn, igi ati okuta, fadakà ati wurà, ti o wà lãrin wọn.)
18 Ki ẹnikẹni ki o má ba wà ninu nyin, ọkunrin, tabi obinrin, tabi idile, tabi ẹ̀ya, ti àiya rẹ̀ ṣí kuro lọdọ OLUWA Ọlọrun wa li oni, lati lọ isìn oriṣa awọn orilẹ-ède wọnyi; ki gbòngbo ti nyọ orõro ati iwọ, ki o má ba wà ninu nyin;
19 Yio si ṣe, nigbati o ba gbọ́ ọ̀rọ egún yi, ti o sure fun ara rẹ̀ ninu àiya rẹ̀, wipe, Emi o ní alafia, bi emi tilẹ nrìn ninu agídi ọkàn mi, lati run tutù pẹlu gbigbẹ:
20 OLUWA ki yio darijì i, ṣugbọn nigbana ni ibinu OLUWA ati owú rẹ̀ yio gbona si ọkunrin na, ati gbogbo egún wọnyi ti a kọ sinu iwé yi ni yio bà lé e, OLUWA yio si nù orukọ rẹ̀ kuro labẹ ọrun.
21 OLUWA yio si yà a si ibi kuro ninu gbogbo ẹ̀ya Israeli, gẹgẹ bi gbogbo egún majẹmu, ti a kọ sinu iwé ofin yi.
22 Ati iran ti mbọ̀, awọn ọmọ nyin ti yio dide lẹhin nyin, ati alejò ti yio ti ilẹ jijìn wá, yio si wi, nigbati nwọn ba ri iyọnu ilẹ na, ati àrun na, ti OLUWA mu bá a;