10 Gbogbo ilu pẹtẹlẹ̀ na, ati gbogbo Gileadi, ati gbogbo Baṣani, dé Saleka ati Edrei, awọn ilu ilẹ ọba Ogu ni Baṣani.
11 (Ogu ọba Baṣani nikanṣoṣo li o sá kù ninu awọn omirán iyokù; kiyesi i, akete rẹ̀ jẹ́ akete irin; kò ha wà ni Rabba ti awọn ọmọ Ammoni? igbọnwọ mẹsan ni gigùn rẹ̀, igbọnwọ mẹrin si ni ibú rẹ̀, ni igbọnwọ ọkunrin.)
12 Ati ilẹ na yi, ti awa gbà ni ìgbana, lati Aroeri, ti mbẹ lẹba afonifoji Arnoni, ati àbọ òke Gileadi, ati ilu inu rẹ̀, ni mo fi fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi:
13 Ati iyokù Gileadi, ati gbogbo Baṣani, ilẹ ọba Ogu, ni mo fi fun àbọ ẹ̀ya Manasse; gbogbo ẹkùn Argobu, pẹlu gbogbo Baṣani. (Ti a ma pè ni ilẹ awọn omirán.
14 Jairi ọmọ Manasse mú gbogbo ilẹ Argobu, dé opinlẹ Geṣuri ati Maakati; o si sọ wọn, ani Baṣan, li orukọ ara rẹ̀, ni Haffotu-jairi titi, di oni.)
15 Mo si fi Gileadi fun Makiri.
16 Ati awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi ni mo fi fun lati Gileadi, ani dé afonifoji Arnoni, agbedemeji afonifoji, ati opinlẹ rẹ̀; ani dé odò Jaboku, ti iṣe ipinlẹ awọn ọmọ Ammoni;