15 Ṣugbọn Jeṣuruni sanra tán, o si tapa: iwọ sanra tán, iwọ kì tan, ọrá bò ọ tán: nigbana li o kọ̀ Ọlọrun ti o dá a, o si gàn Apata ìgbala rẹ̀.
16 Nwọn fi oriṣa mu u jowú, ohun irira ni nwọn fi mu u binu.
17 Nwọn rubọ si iwin-buburu ti ki iṣe Ọlọrun, si oriṣa ti nwọn kò mọ̀ rí, si oriṣa ti o hù ni titun, ti awọn baba nyin kò bẹ̀ru.
18 Apata ti o bi ọ ni iwọ kò ranti, iwọ si ti gbagbé Ọlọrun ti o dá ọ.
19 OLUWA si ri i, o si korira wọn, nitori ìwa-imunibinu awọn ọmọkunrin rẹ̀, ati ti awọn ọmọbinrin rẹ̀.
20 O si wipe, Emi o pa oju mi mọ́ kuro lara wọn, emi o si ma wò bi igbẹhin wọn yio ti ri; nitori iran alagídi ni nwọn, awọn ọmọ ninu ẹniti kò sí igbagbọ.
21 Nwọn ti fi ohun ti ki iṣe Ọlọrun mu mi jowú; nwọn si fi ohun asan wọn mu mi binu: emi o si fi awọn ti ki iṣe enia mu wọn jowú; emi o si fi aṣiwere orilẹ-ède mu wọn binu.