33 Ọti-waini wọn iwọ ti dragoni ni, ati oró mimu ti pamọlẹ̀.
34 Eyi ki a tojọ sọdọ mi ni ile iṣura, ti a si fi èdidi dì ninu iṣura mi?
35 Ti emi ni igbẹsan, ati ẹsan, li akokò ti ẹsẹ̀ wọn yio yọ́: nitoriti ọjọ́ idamu wọn sunmọtosi, ohun ti o si mbọ̀ wa bá wọn nyára wá.
36 Nitoripe OLUWA yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, yio si kãnu awọn iranṣẹ rẹ̀; nigbati o ba ri pe agbara wọn lọ tán, ti kò si sí ẹnikan ti a sé mọ́, tabi ti o kù.
37 On o si wipe, Nibo li oriṣa wọn gbé wà, apata ti nwọn gbẹkẹle:
38 Ti o ti jẹ ọrá ẹbọ wọn, ti o ti mu ọti-waini ẹbọ ohunmimu wọn? jẹ ki nwọn dide ki nwọn si ràn nyin lọwọ, ki nwọn ṣe àbo nyin.
39 Wò o nisisiyi pe Emi, ani Emi ni, kò si sí ọlọrun pẹlu mi: mo pa, mo si sọ di ãye; mo ṣalọgbẹ, mo si mu jiná; kò si sí ẹnikan ti o le gbà silẹ li ọwọ́ mi.