39 Wò o nisisiyi pe Emi, ani Emi ni, kò si sí ọlọrun pẹlu mi: mo pa, mo si sọ di ãye; mo ṣalọgbẹ, mo si mu jiná; kò si sí ẹnikan ti o le gbà silẹ li ọwọ́ mi.
40 Nitoripe mo gbé ọwọ́ mi soke ọrun, mo si wipe, Bi Emi ti wà titilai.
41 Bi mo ba si pọ́n idà didan mi, ti mo ba si fi ọwọ́ mi lé idajọ; emi o san ẹsan fun awọn ọtá mi, emi o radi i fun awọn ti o korira mi.
42 Emi o mu ọfà mi rin fun ẹ̀jẹ, idà mi o si jẹ ẹran; ninu ẹ̀jẹ ẹni pipa ati ti igbekun, lati ori awọn aṣaju ọtá.
43 Ẹ ma yọ̀, ẹnyin orilẹ-ède, pẹlu awọn enia rẹ̀: nitoripe on o gbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ̀, yio si gbẹsan lara awọn ọtá rẹ̀, yio si ṣètutu fun ilẹ rẹ̀, ati fun awọn enia rẹ̀.
44 Mose si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi li etí awọn enia na, on, ati Hoṣea ọmọ Nuni.
45 Mose si pari sisọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo Israeli: