46 O si wi fun wọn pe, Ẹ gbé ọkàn nyin lé gbogbo ọ̀rọ ti mo sọ lãrin nyin li oni; ti ẹnyin o palaṣẹ fun awọn ọmọ nyin lati ma kiyesi ati ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi.
47 Nitoripe ki iṣe ohun asan fun nyin; nitoripe ìye nyin ni, ati nipa eyi li ẹnyin o mu ọjọ́ nyin pẹ ni ilẹ na, nibiti ẹnyin ngòke Jordani lọ lati gbà a.
48 OLUWA si sọ fun Mose li ọjọ́ na gan, wipe,
49 Gùn òke Abarimu yi lọ, si òke Nebo, ti mbẹ ni ilẹ Moabu, ti o kọjusi Jeriko; ki o si wò ilẹ Kenaani, ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli ni iní.
50 Ki o si kú lori òke na, nibiti iwọ ngùn lọ, ki a si kó ọ jọ sọdọ awọn enia rẹ; bi Aaroni arakunrin rẹ ti kú li òke Horu, ti a si kó o jọ sọdọ awọn enia rẹ̀:
51 Nitoriti ẹnyin ṣẹ̀ si mi lãrin awọn ọmọ Israeli ni ibi omi Meriba-Kadeṣi, li aginjù Sini; nitoriti ẹnyin kò yà mi simimọ́ lãrin awọn ọmọ Israeli.
52 Ṣugbọn iwọ o ri ilẹ na niwaju rẹ; ṣugbọn iwọ ki yio lọ sibẹ̀, si ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli.