5 Nwọn ti bà ara wọn jẹ́ lọdọ rẹ̀, nwọn ki iṣe ọmọ rẹ̀, àbuku wọn ni; iran arekereke ati wiwọ́ ni nwọn.
6 Bayi li ẹnyin o ha san ẹsan fun OLUWA, ẹnyin aṣiwere enia ati alaigbọn? On ha kọ́ ni baba rẹ ti o rà ọ? on li o dá ọ, on li o si fi ẹsẹ̀ rẹ mulẹ?
7 Ranti ọjọ́ igbãni, ronu ọdún iraniran: bi baba rẹ lere yio si fihàn ọ; bi awọn àgba rẹ, nwọn o si sọ fun ọ.
8 Nigbati Ọga-ogo pín iní fun awọn orilẹ-ède, nigbati o tu awọn ọmọ enia ká, o pàla awọn enia na gẹgẹ bi iye awọn ọmọ Israeli.
9 Nitoripe ipín ti OLUWA li awọn enia rẹ̀; Jakobu ni ipín iní rẹ̀.
10 O ri i ni ilẹ aṣalẹ̀, ati ni aginjù nibiti ẹranko nke; o yi i ká, o tọju rẹ̀, o pa a mọ́ bi ẹyin oju rẹ̀:
11 Bi idì ti irú itẹ́ rẹ̀, ti iràbaba sori ọmọ rẹ̀, ti inà iyẹ́-apa rẹ̀, ti igbé wọn, ti ima gbé wọn lọ lori iyẹ́-apa rẹ̀: