2 O si wipe, OLUWA ti Sinai wá, o si yọ si wọn lati Seiri wá; o tàn imọlẹ jade lati òke Parani wá, o ti ọdọ ẹgbẹgbãrun awọn mimọ́ wá: lati ọwọ́ ọtún rẹ̀ li ofin kan amubĩná ti jade fun wọn wá.
3 Nitõtọ, o fẹ́ awọn enia na; gbogbo awọn enia mimọ́ rẹ̀ wà li ọwọ́ rẹ. Nwọn si joko li ẹsẹ̀ rẹ; olukuluku ni yio gbà ninu ọ̀rọ rẹ.
4 Mose fi ofin kan lelẹ li aṣẹ fun wa, iní ti ijọ enia Jakobu.
5 O si jẹ́ ọba ni Jeṣuruni, nigbati olori awọn enia, awọn ẹ̀ya Israeli pejọ pọ̀.
6 Ki Reubeni ki o yè, ki o máṣe kú; ki enia rẹ̀ ki o máṣe mọniwọn.
7 Eyi si ni ti Judah: o si wipe, OLUWA, gbọ́ ohùn Judah, ki o si mú u tọ̀ awọn enia rẹ̀ wá: ki ọwọ́ rẹ̀ ki o to fun u; ki iwọ ki o si ṣe iranlọwọ fun u lọwọ awọn ọtá rẹ̀.
8 Ati niti Lefi o wipe, Jẹ ki Tummimu ati Urimu rẹ ki o wà pẹlu ẹni mimọ́ rẹ, ẹniti iwọ danwò ni Massa, ati ẹniti iwọ bá jà li omi Meriba;