21 O si yàn apá ikini fun ara rẹ̀, nitoripe nibẹ̀ li a fi ipín olofin pamọ́ si; o si wá pẹlu awọn olori enia na, o si mú ododo OLUWA ṣẹ, ati idajọ rẹ̀ pẹlu Israeli.
22 Ati niti Dani o wipe, Ọmọ kiniun ni Dani: ti nfò lati Baṣani wá.
23 Ati niti Naftali o wipe, Iwọ Naftali, ti ojurere tẹ́lọrùn, ti o si kún fun ibukún OLUWA: gbà ìha ìwọ-õrùn ati gusù.
24 Ati niti Aṣeri o wipe, Ibukún ọmọ niti Aṣeri; ki on ki o si jẹ́ itẹwọgba fun awọn arakunrin rẹ̀, ki on ki o si ma rì ẹsẹ̀ rẹ̀ sinu oróro.
25 Bàta rẹ yio jasi irin ati idẹ; ati bi ọjọ́ rẹ, bẹ̃li agbara rẹ yio ri.
26 Kò sí ẹniti o dabi Ọlọrun, iwọ Jeṣuruni, ti ngùn ọrun fun iranlọwọ rẹ, ati ninu ọlanla rẹ̀ li oju-ọrun.
27 Ọlọrun aiyeraiye ni ibugbé rẹ, ati nisalẹ li apa aiyeraiye wà: on si tì ọtá kuro niwaju rẹ, o si wipe, Ma parun.