3 Nitõtọ, o fẹ́ awọn enia na; gbogbo awọn enia mimọ́ rẹ̀ wà li ọwọ́ rẹ. Nwọn si joko li ẹsẹ̀ rẹ; olukuluku ni yio gbà ninu ọ̀rọ rẹ.
4 Mose fi ofin kan lelẹ li aṣẹ fun wa, iní ti ijọ enia Jakobu.
5 O si jẹ́ ọba ni Jeṣuruni, nigbati olori awọn enia, awọn ẹ̀ya Israeli pejọ pọ̀.
6 Ki Reubeni ki o yè, ki o máṣe kú; ki enia rẹ̀ ki o máṣe mọniwọn.
7 Eyi si ni ti Judah: o si wipe, OLUWA, gbọ́ ohùn Judah, ki o si mú u tọ̀ awọn enia rẹ̀ wá: ki ọwọ́ rẹ̀ ki o to fun u; ki iwọ ki o si ṣe iranlọwọ fun u lọwọ awọn ọtá rẹ̀.
8 Ati niti Lefi o wipe, Jẹ ki Tummimu ati Urimu rẹ ki o wà pẹlu ẹni mimọ́ rẹ, ẹniti iwọ danwò ni Massa, ati ẹniti iwọ bá jà li omi Meriba;
9 Ẹniti o wi niti baba rẹ̀, ati niti iya rẹ̀ pe, Emi kò ri i; bẹ̃ni kò si jẹwọ awọn arakunrin rẹ̀, bẹ̃ni kò si mọ̀ awọn ọmọ rẹ̀: nitoriti nwọn kiyesi ọ̀rọ rẹ, nwọn si pa majẹmu rẹ mọ́.