3 Oju nyin ti ri ohun ti OLUWA ṣe nitori Baali-peori: nitoripe gbogbo awọn ọkunrin ti o tẹlé Baali-peori lẹhin, OLUWA Ọlọrun rẹ ti run wọn kuro lãrin rẹ.
4 Ṣugbọn ẹnyin ti o faramọ́ OLUWA Ọlọrun nyin, gbogbo nyin mbẹ lãye li oni.
5 Wò o, emi ti kọ́ nyin ni ìlana ati idajọ, bi OLUWA Ọlọrun mi ti paṣẹ fun mi, pe ki ẹnyin ki o le ma ṣe bẹ̃ ni ilẹ na nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a.
6 Nitorina ẹ pa wọn mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn; nitoripe eyi li ọgbọ́n nyin ati oye nyin li oju awọn orilẹ-ède, ti yio gbọ́ gbogbo ìlana wọnyi, ti yio si wipe, Ọlọgbọ́n ati amoye enia nitõtọ ni orilẹ-ède nla yi.
7 Nitori orilẹ-ède nla wo li o wà, ti o ní Ọlọrun sunmọ wọn to, bi OLUWA Ọlọrun wa ti ri ninu ohun gbogbo ti awa kepè e si?
8 Ati orilẹ-ède nla wo li o si wà, ti o ní ìlana ati idajọ ti iṣe ododo to bi gbogbo ofin yi, ti mo fi siwaju nyin li oni?
9 Kìki ki iwọ ki o ma kiyesara rẹ, ki o si ṣọ́ ọkàn rẹ gidigidi, ki iwọ ki o má ba gbagbé ohun ti oju rẹ ti ri, ati ki nwọn ki o má ba lọ kuro li àiya rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; ṣugbọn ki iwọ ki o ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ;