44 Eyi li ofin na ti Mose filelẹ niwaju awọn ọmọ Israeli:
45 Wọnyi li ẹrí, ati ìlana, ati idajọ, ti Mose filelẹ fun awọn ọmọ Israeli, lẹhin igbati nwọn ti Egipti jade wá;
46 Ni ìha ẹ̀bá Jordani, ni afonifoji ti o kọjusi Beti-peori, ni ilẹ Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni, ẹniti Mose ati awọn ọmọ Israeli kọlù, lẹhin igbati nwọn ti Egipti jade wá:
47 Nwọn si gbà ilẹ rẹ̀, ati ilẹ Ogu ọba Baṣani, awọn ọba Amori mejeji ti mbẹ ni ìha ẹ̀bá Jordani si ìha ìla-õrùn;
48 Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ani dé òke Sioni (ti iṣe Hermoni,)
49 Ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ nì, ni ìha ẹ̀bá Jordani ni ìha ìla-õrùn, ani dé okun pẹtẹlẹ̀ nì, nisalẹ awọn orisun Pisga.