21 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si aya ẹnikeji rẹ; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si ile ẹnikeji rẹ, oko rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ̀ obinrin, akọmalu rẹ̀, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, ati ohun gbogbo ti iṣe ti ẹnikeji rẹ.
22 Ọ̀rọ wọnyi ni OLUWA sọ fun gbogbo ijọ nyin lori òke lati ãrin iná, awọsanma, ati lati inu òkunkun biribiri wá, pẹlu ohùn nla: kò si fi kún u mọ́. O si kọ wọn sara walã okuta meji, o si fi wọn fun mi.
23 O si ṣe, nigbati ẹnyin gbọ́ ohùn nì lati ãrin òkunkun na wá, ti òke na si njó, ti ẹnyin sunmọ ọdọ mi, gbogbo olori awọn ẹ̀ya nyin, ati awọn àgba nyin:
24 Ẹnyin si wipe, Kiyesi i, OLUWA Ọlọrun wa fi ogo rẹ̀ ati titobi rẹ̀ hàn wa, awa si ti gbọ́ ohùn rẹ̀ lati ãrin iná wá: awa ti ri li oni pe, OLUWA a ma ba enia sọ̀rọ̀, on a si wà lãye.
25 Njẹ nisisiyi ẽṣe ti awa o fi kú? nitoripe iná nla yi yio jó wa run: bi awa ba tun gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa, njẹ awa o kú.
26 Nitoripe tani mbẹ ninu gbogbo araiye ti o ti igbọ́ ohùn Ọlọrun alãye ti nsọ̀rọ lati ãrin iná wá, bi awa ti gbọ́, ti o si wà lãye?
27 Iwọ sunmọtosi, ki o si gbọ́ gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun wa yio wi: ki iwọ ki o sọ fun wa gbogbo ohun ti OLUWA Ọlọrun wa yio sọ fun ọ: awa o si gbọ́, awa o si ṣe e.