22 Ọ̀rọ wọnyi ni OLUWA sọ fun gbogbo ijọ nyin lori òke lati ãrin iná, awọsanma, ati lati inu òkunkun biribiri wá, pẹlu ohùn nla: kò si fi kún u mọ́. O si kọ wọn sara walã okuta meji, o si fi wọn fun mi.
23 O si ṣe, nigbati ẹnyin gbọ́ ohùn nì lati ãrin òkunkun na wá, ti òke na si njó, ti ẹnyin sunmọ ọdọ mi, gbogbo olori awọn ẹ̀ya nyin, ati awọn àgba nyin:
24 Ẹnyin si wipe, Kiyesi i, OLUWA Ọlọrun wa fi ogo rẹ̀ ati titobi rẹ̀ hàn wa, awa si ti gbọ́ ohùn rẹ̀ lati ãrin iná wá: awa ti ri li oni pe, OLUWA a ma ba enia sọ̀rọ̀, on a si wà lãye.
25 Njẹ nisisiyi ẽṣe ti awa o fi kú? nitoripe iná nla yi yio jó wa run: bi awa ba tun gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa, njẹ awa o kú.
26 Nitoripe tani mbẹ ninu gbogbo araiye ti o ti igbọ́ ohùn Ọlọrun alãye ti nsọ̀rọ lati ãrin iná wá, bi awa ti gbọ́, ti o si wà lãye?
27 Iwọ sunmọtosi, ki o si gbọ́ gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun wa yio wi: ki iwọ ki o sọ fun wa gbogbo ohun ti OLUWA Ọlọrun wa yio sọ fun ọ: awa o si gbọ́, awa o si ṣe e.
28 OLUWA si gbọ́ ohùn ọ̀rọ nyin, nigbati ẹnyin sọ fun mi; OLUWA si sọ fun mi pe, emi ti gbọ́ ohùn ọ̀rọ awọn enia yi, ti nwọn sọ fun ọ: nwọn wi rere ni gbogbo eyiti nwọn sọ.