1 NJẸ wọnyi li ofin, ìlana, ati idajọ, ti OLUWA Ọlọrun nyin ti palaṣẹ lati ma kọ́ nyin, ki ẹnyin ki o le ma ṣe wọn ni ilẹ nibiti ẹnyin gbé nlọ lati gbà a:
2 Ki iwọ ki o le ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa gbogbo ìlana rẹ̀ ati ofin rẹ̀ mọ́, ti emi fi fun ọ, iwọ, ati ọmọ rẹ, ati ọmọ ọmọ rẹ, li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ.
3 Nitorina gbọ́, Israeli, ki o si ma kiyesi i lati ṣe e; ki o le dara fun ọ, ati ki ẹnyin ki o le ma pọ̀si i li ọ̀pọlọpọ, bi OLUWA Ọlọrun awọn baba rẹ ti ṣe ileri fun ọ, ni ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.
4 Gbọ́, Israeli: OLUWA Ọlọrun wa, OLUWA kan ni.
5 Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ.
6 Ati ọ̀rọ wọnyi, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o ma wà ni àiya rẹ: