3 O si rẹ̀ ọ silẹ, o si fi ebi pa ọ, o si fi manna bọ́ ọ, ti iwọ kò mọ̀, bẹ̃ni awọn baba rẹ kò mọ̀; ki o le mu ọ mọ̀ pe enia kò ti ipa onjẹ nikan wà lãye, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ ti o ti ẹnu OLUWA jade li enia wà lãye.
4 Aṣọ rẹ kò gbó mọ́ ọ lara, bẹ̃li ẹsẹ̀ rẹ kò wú, lati ogoji ọdún yi wá.
5 Ki iwọ ki o si mọ̀ li ọkàn rẹ pe, bi enia ti ibá ọmọ rẹ̀ wi, bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun rẹ bá ọ wi.
6 Ki iwọ ki o pa ofin OLUWA Ọlọrun rẹ mọ́, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀, ati lati ma bẹ̀ru rẹ̀.
7 Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ wá sinu ilẹ rere, ilẹ odò omi, ti orisun ati ti abẹ-ilẹ, ti nrú soke lati afonifoji ati òke jade wa;
8 Ilẹ alikama ati ọkà-barle, ati àjara ati igi ọpọtọ ati igi pomegranate; ilẹ oróro olifi, ati oyin;
9 Ilẹ ninu eyiti iwọ ki o fi ìṣẹ jẹ onjẹ, iwọ ki yio fẹ ohun kan kù ninu rẹ̀; ilẹ ti okuta rẹ̀ iṣe irin, ati lati inu òke eyiti iwọ o ma wà idẹ.