22 Ati ni Tabera, ati ni Massa, ati ni Kibrotu-hattaafa, ẹnyin mu OLUWA binu.
23 Nigbati OLUWA rán nyin lati Kadeṣi-barnea lọ, wipe, Gòke lọ ki o si gbà ilẹ na ti mo fi fun nyin; nigbana li ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ OLUWA Ọlọrun nyin, ẹnyin kò si gbà a gbọ́, bẹ̃li ẹnyin kò si fetisi ohùn rẹ̀.
24 Ẹnyin ti nṣọ̀tẹ si OLUWA lati ọjọ́ ti mo ti mọ̀ nyin.
25 Mo si wolẹ niwaju OLUWA li ogoji ọsán ati li ogoji oru, bi mo ti wolẹ niṣaju; nitoriti OLUWA wipe, on o run nyin.
26 Mo si gbadura sọdọ OLUWA wipe, Oluwa ỌLỌRUN, máṣe run awọn enia rẹ ati iní rẹ, ti iwọ ti fi titobi rẹ̀ ràsilẹ, ti iwọ mú lati Egipti jade wá pẹlu ọwọ́ agbara.
27 Ranti Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu awọn iranṣẹ rẹ; máṣe wò agídi awọn enia yi, tabi ìwabuburu wọn, tabi ẹ̀ṣẹ wọn:
28 Ki awọn enia ilẹ na ninu eyiti iwọ ti mú wa jade wá ki o má ba wipe, Nitoriti OLUWA kò le mú wọn dé ilẹ na ti o ti ṣe ileri fun wọn, ati nitoriti o korira wọn, li o ṣe mú wọn jade wá lati pa wọn li aginjù.