Deu 9:3-9 YCE

3 Iwọ o si mọ̀ li oni pe, OLUWA Ọlọrun rẹ on ni ngòke ṣaju rẹ lọ bi iná ajonirun; yio pa wọn run, on o si rẹ̀ wọn silẹ niwaju rẹ: iwọ o si lé wọn jade, iwọ o si pa wọn run kánkán, bi OLUWA ti wi fun ọ.

4 Máṣe sọ li ọkàn rẹ, lẹhin igbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba tì wọn jade kuro niwaju rẹ, wipe, Nitori ododo mi ni OLUWA ṣe mú mi wá lati gbà ilẹ yi: ṣugbọn nitori ìwabuburu awọn orilẹ-ède wọnyi ni OLUWA ṣe lé wọn jade kuro niwaju rẹ.

5 Ki iṣe nitori ododo rẹ, tabi nitori pipé ọkàn rẹ, ni iwọ fi nlọ lati gbà ilẹ wọn: ṣugbọn nitori ìwabuburu awọn orilẹ-ède wọnyi li OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe lé wọn kuro niwaju rẹ, ati ki o le mu ọ̀rọ na ṣẹ ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ, Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu.

6 Nitorina ki o yé ọ pe, OLUWA Ọlọrun rẹ kò fi ilẹ rere yi fun ọ lati ní i nitori ododo rẹ; nitoripe enia ọlọrùn lile ni iwọ.

7 Ranti, máṣe gbagbé, bi iwọ ti mu OLUWA Ọlọrun rẹ binu li aginjù: lati ọjọ́ na ti iwọ ti jade kuro ni ilẹ Egipti, titi ẹnyin fi dé ihin yi, ẹnyin ti nṣọ̀tẹ si OLUWA.

8 Ati ni Horebu ẹnyin mu OLUWA binu, OLUWA si binu si nyin tobẹ̃ ti o fẹ́ pa nyin run.

9 Nigbati mo gòke lọ sori òke lati gbà walã okuta wọnni, ani walã majẹmu nì ti OLUWA bá nyin dá, nigbana mo gbé ogoji ọsán, ati ogoji oru lori òke na, emi kò jẹ onjẹ, bẹ̃li emi kò mu omi.