1 ABRAHAMU si gbó, o si pọ̀ li ọjọ́: OLUWA si ti busi i fun Abrahamu li ohun gbogbo.
2 Abrahamu si wi fun iranṣẹ rẹ̀, agba ile rẹ̀ ti o ṣe olori ohun gbogbo ti o ni pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ọwọ rẹ si abẹ itan mi;
3 Emi o si mu ọ fi OLUWA bura, Ọlọrun ọrun, ati Ọlọrun aiye, pe iwọ ki yio fẹ́ aya fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani, lãrin awọn ẹniti mo ngbé:
4 Ṣugbọn iwọ o lọ si ilẹ mi, ati si ọdọ awọn ará mi, ki iwọ ki o si fẹ́ aya fun Isaaki, ọmọ mi.
5 Iranṣẹ na si wi fun u pe, Bọya obinrin na ki yio fẹ́ ba mi wá si ilẹ yi: mo ha le mu ọmọ rẹ pada lọ si ilẹ ti iwọ gbé ti wá?