39 Farao si wi fun Josefu pe, Niwọnbi Ọlọrun ti fi gbogbo nkan yi hàn ọ, kò sí ẹniti o ṣe amoye ati ọlọgbọ́n bi iwọ:
40 Iwọ ni yio ṣe olori ile mi, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ li a o si ma ṣe akoso awọn enia mi: itẹ́ li emi o fi tobi jù ọ lọ:
41 Farao si wi fun Josefu pe, Wò o, emi fi ọ jẹ́ olori gbogbo ilẹ Egipti.
42 Farao si bọ́ oruka ọwọ́ rẹ̀ kuro, o si fi bọ̀ Josefu li ọwọ́, o si wọ̀ ọ li aṣọ ọ̀gbọ daradara, o si fi ẹ̀wọn wurà si i li ọrùn;
43 O si mu u gùn kẹkẹ́ keji ti o ní; nwọn si nké niwaju rẹ̀ pe, Kabiyesi: o si fi i jẹ́ olori gbogbo ilẹ Egipti.
44 Farao si wi fun Josefu pe, Emi ni Farao, lẹhin rẹ ẹnikẹni kò gbọdọ gbé ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ soke ni gbogbo ilẹ Egipti.
45 Farao si sọ orukọ Josefu ni Safnati-paanea; o si fi Asenati fun u li aya, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni. Josefu si jade lọ si ori ilẹ Egipti.