1 Ní ọjọ́ kan náà, Jésù kúrò ní ilé, ó jókòó sí etí òkun.
2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀-ojú omi, ó jókòó, gbogbo ènìyàn sì dúró létí òkun.
3 Nígbà náà ni ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe bá wọn sọ̀rọ̀, wí pé: “Àgbẹ̀ kan jáde lọ gbin irúgbìn sínú oko rẹ̀.
4 Bí ó sì ti gbin irúgbìn náà, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì jẹ ẹ́.
5 Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ orí àpáta, níbi ti kò sí erùpẹ̀ púpọ̀. Àwọn irúgbìn náà sì dàgbà sókè kíákíá, nítorí erùpẹ̀ kò pọ̀ lórí wọn.
6 Ṣùgbọ́n nígbà tí òòrùn gòkè, oòrùn gbígbóná jó wọn, gbogbo wọ sì rọ, wọ́n kú nítorí wọn kò ni gbòǹgbò.