25 Ṣùgbọ́n ní òru ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn, ọ̀ta rẹ̀ wá sí oko náà ó sì gbin èpò sáàrin àlìkámà, ó sì bá tirẹ̀ lọ.
26 Nígbà tí àlíkámà náà bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà, tí ó sì so èso, nígbà náà ni èpò náà fi ara hàn.
27 “Àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ àgbẹ̀ náà wá, wọ́n sọ fún un pé, ‘Ọ̀gá, irúgbìn rere kọ́ ni ìwọ ha gbìn sí oko rẹ nì? Báwo ni èpò ṣe wà níbẹ̀ nígbà náà?’
28 “Ó sọ fún wọn pé, ‘Ọ̀tá ni ó ṣe èyí.’“Wọ́n tún bí i pé, ‘Ǹjẹ́ ìwọ ha fẹ́ kí a tu èpò náà kúrò?’
29 “Ó dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá, nítorí bí ẹ̀yin bá ń tu èpò kúrò, ẹ ó tu àlìkámà dànù pẹ̀lú rẹ̀.
30 Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì máa dàgbà pọ̀, títí di àsìkò ìkórè. Èmi yóò sọ fún àwọn olùkórè náà láti kọ́kọ́ ṣa àwọn èpò kúrò kí wọ́n sì dì wọ́n ní ìtí, kí a sì sun wọn, kí wọ́n sì kó àlìkámà sínú àká mi.’ ”
31 Jésù tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí èso hóró músítádì, èyí tí ọkùnrin kan mú tí ó gbìn sínú oko rẹ̀.