33 Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí yíìsìtì tí obìnrin kan mú tí ó pò mọ́ ìyẹ̀fun (ìyẹ̀fun) púpọ̀ títí tí gbogbo rẹ fi di wíwú.”
34 Òwe ni Jésù fi sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, òwe ni ó fi bá wọn sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tó sọ.
35 Kí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì sọ lé wá sí ìmúsẹ pé:“Èmi yóò ya ẹnu mi láti fi òwe sọ̀rọ̀.Èmi yóò sọ àwọn ohun tí ó farasin láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá.”
36 Lẹ́yìn náà ó sì fi ọ̀pọ̀ ènìyàn sílẹ̀ lóde, ó wọ ilé lọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn wí pé, “Ṣàlàyé òwe èpò inú oko fún wa”.
37 Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ọmọ ènìyàn ni ẹni tí ó ń fúnrúgbìn rere.
38 Ayé ni oko náà; irúgbìn rere ni àwọn ènìyàn ti ìjọba ọ̀run. Èpò ni àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ti èṣù,
39 ọ̀tá tí ó gbin àwọn èpò sáàrin àlìkámà ni èṣù. Ìkórè ni òpin ayé, àwọn olùkórè sì ní àwọn ańgẹ́lì.