38 Ayé ni oko náà; irúgbìn rere ni àwọn ènìyàn ti ìjọba ọ̀run. Èpò ni àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ti èṣù,
39 ọ̀tá tí ó gbin àwọn èpò sáàrin àlìkámà ni èṣù. Ìkórè ni òpin ayé, àwọn olùkórè sì ní àwọn ańgẹ́lì.
40 “Gẹ́gẹ́ bí a ti kó èpò jọ, tí a sì sun ún nínú iná, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé.
41 Ọmọ Ènìyàn yóò ran àwọn ańgẹ́lì rẹ̀, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tó ń mú ni dẹ́sẹ̀ kúrò ní ìjọba rẹ̀ àti gbogbo ènìyàn búburú.
42 Wọn yóò sì sọ wọ́n sí inú iná ìléru, níbi ti ẹkún òun ìpayínkeke yóò gbé wà.
43 Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò máa ràn bí òòrùn ní ìjọba Baba wọn. Ẹni tí ó bá létí, jẹ́ kí ó gbọ́.
44 “Ìjọba ọ̀run sì dàbí ìṣúra kan tí a fi pamọ́ sínú oko. Nígbà tí ọkùnrin kan rí i ó tún fi í pamọ́. Nítorí ayọ̀ rẹ̀, ó ta gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó ra oko náà.