19 Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-un àti ẹja méjì. Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run. Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn.
20 Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kó àjẹkù jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá.
21 Iye àwọn ènìyàn ni ọjọ́ náà jẹ́ ẹgbẹẹ́dọ́gbọ̀n (5,000) ọkùnrin, Láì ka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.
22 Lẹ́sẹ̀kẹ́sẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n bọ sínú ọkọ̀ wọn, àti kí wọ́n máa kọjá lọ ṣáájú rẹ̀ sí òdì kejì. Òun náà dúró lẹ́yìn láti tú àwọn ènìyàn ká lọ sí ilé wọn
23 Lẹ́yìn tí ó tú ìjọ ènìyàn ká tán, ó gun orí òkè lọ fúnra rẹ̀ láti lọ gba àdúrà. Nígbà tí ilẹ̀ sú, óun wà ni nìkan níbẹ̀,
24 ní àkókò yìí ọkọ ojú-omi náà ti rin jìnnà sí etí bèbè òkun, tí ìjì omi ń tì í síwá sẹ́yìn, nítorí ìjì ṣe ọwọ́ òdì sí wọn.
25 Ní déédé agogo mẹ́rin òwúrọ̀, Jésù tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi.