21 Nígbà náà ni Pétérù wá sọ́dọ̀ Jésù, ó béèrè pé, “Olúwa, nígbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mi, tí èmi yóò sì dáríjì í? Tàbí ní ìgbà méje ni?”
22 Jésù dáhùn pé, “Mo wí fún ọ, kì í se ìgbà méje, ṣùgbọ́n ní ìgbà àádọ́rin méje;
23 “Nítorí náà, ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ se ìṣirò pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀.
24 Bí ó ti ń ṣe èyí, a mú ajigbésè kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbàáárún (10,000) talẹ́ńtì.
25 Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà.
26 “Nígbà náà ni ọmọ-ọ̀dọ̀ náà wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ. ‘Ó bẹ̀bẹ̀ pé, mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san gbogbo rẹ̀ fún ọ.’
27 Nígbà náà, ni olúwa ọmọ-ọ̀dọ̀ náà sì ṣàánú fún un. Ó tú u sílẹ̀, ó sì fi gbésè náà jì í.