23 “Nítorí náà, ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ se ìṣirò pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀.
24 Bí ó ti ń ṣe èyí, a mú ajigbésè kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbàáárún (10,000) talẹ́ńtì.
25 Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà.
26 “Nígbà náà ni ọmọ-ọ̀dọ̀ náà wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ. ‘Ó bẹ̀bẹ̀ pé, mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san gbogbo rẹ̀ fún ọ.’
27 Nígbà náà, ni olúwa ọmọ-ọ̀dọ̀ náà sì ṣàánú fún un. Ó tú u sílẹ̀, ó sì fi gbésè náà jì í.
28 “Ṣùgbọ́n bí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà ti jáde lọ, ó rí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún dínárì, ó gbé ọwọ́ lé e, ó fún un ní ọrùn, ó wí pé ‘san gbéṣè tí o jẹ mí lójú ẹṣẹ̀.’
29 “Arákùnrin náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ.’