3 Nígbà tí ọba Hẹ́rọ́dù sì gbọ́ èyí, ìdáàmú bá a àti gbogbo àwọn ara Jerúsálémù pẹ̀lú rẹ̀
4 Nígbà tí ó sì pe àwọn olórí àlùfàá àti àwọn olùkọ́ òfin jọ, ó bi wọ́n léèrè níbi ti a ó gbé bí Kírísítì?
5 Wọ́n sì wí pé, “Ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Jùdíà, èyí ni ohun tí wòlíì ti kọ ìwé rẹ̀ pé:
6 “ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ní ilẹ̀ Jùdíà,ìwọ kò kéré jù láàrin àwọn ọmọ aládé Jùdíà;nítorí láti inú rẹ ni Baálẹ̀ kan yóò ti jáde,Ẹni ti yóò ṣe àkóso lórí Ísírẹ́lì, àwọn ènìyàn mi.’ ”
7 Nígbà náà ni Hérọ́dù ọba pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wádìí ni ọwọ́ wọn, àkókò náà gan-an tí wọ́n kọ́kọ́ rí ìràwọ̀.
8 Ó sì rán wọn lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó sì wí pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí fínnífínní ní ti ọmọ náà tí a bí. Lẹ́yìn tí ẹ bá sì rí i, ẹ padà wá sọ fún mi, kí èmi náà le lọ foríbalẹ̀ fún un.”
9 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, sì wò ó, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí láti ìhà ìlà-oòrùn wá, ó ṣáájú wọn, títítí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ náà gbé wà.