16 “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ìkẹyìn yóò di ẹni ìṣáájú, ẹni ìṣáájú yóò sì di ẹni ìkẹyìn.”
17 Bí Jésù ti ń gòkè lọ sí Jerúsálémù, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí apá kan ó sì wí pé,
18 “Wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù. Ó sọ fún wọn pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá mi lẹ́bi ikú.
19 Wọn yóò sì lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà àti láti nàa án, àti láti kàn mi mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta, yóò jí dìde.”
20 Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sébédè bá àwọn ọmọ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jésù, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, o béèrè fún ojú rere rẹ̀.
21 Jésù béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”Ó sì dáhùn pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ mi méjèèjì jókòó ní apá ọ̀tún àti apá òsì lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ?”
22 Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn ó sì wí pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀yin ń béèrè, ẹ̀yin ha le mu nínú aago tí èmi ó mu?”Wọ́n dáhùn pé, “Àwa lè mu ún.”