1 Bí wọ́n ti sún mọ́ Jérúsalẹmu, tí wọ́n dé ìtòòsí ìlú Bẹ́tífágè ní orí òkè Ólífì, Jésù sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì,
2 Ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí ìletò tó wà ni tòòsí yín, ẹ̀yin yóò rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ti wọ́n so pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ sì mú wọn wá fún mi.
3 Bí ẹnikẹ́ni bá sì béèrè ìdí tí ẹ fi ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ sáà wí pé, Olúwa ní wọn-ọ́n lò, òun yóò sì rán wọn lọ.”
4 Èyí ṣẹlẹ̀ láti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì ṣẹ pé:
5 “Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Síónì pé,‘Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,ní ìrẹ̀lẹ̀, ó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,àti lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’ ”
6 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sí lọ, wọ́n ṣe bí Jésù ti sọ fún wọn