Mátíù 21:31-37 BMY

31 “Nínú àwọn méjèèjì yìí, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba wọn?”Gbogbo wọn sì fohùn ṣọ̀kan pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni.”Jésù wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àwọn agbowó-òde àti àwọn panṣágà yóò wọ ìjọba ọ̀run ṣíwájú yín.

32 Nítorí Jòhánù tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó-òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́.”

33 “Ẹ gbọ́ òwe mìíràn: Baálé ilé kan tí ó gbin àjàrà, ó ṣe ọgbà yìí ká, ó wá ibi ifúntí sínú rẹ̀, ó kọ́ ilé-ìsọ́. Ó sì fi oko náà ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn àgbẹ̀ kan, ó sì lọ sí ìrìnàjò.

34 Nígbà ti àkókò ìkórè súnmọ́, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn àgbẹ̀ náà láti gba èyí ti ó jẹ tirẹ̀ wá.

35 “Ṣùgbọ́n àwọn olágbàtọ́jú sì mú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọn lu ẹnì kínní, wọn pa èkèjì, wọ́n si sọ ẹ̀kẹ́ta ní òkúta.

36 Lẹ́ẹ̀kejì, ó rán àwọn ìránṣẹ́ tí ó pọ̀ ju ti ìṣaájú sí wọn. Wọ́n sì tún ṣe bí ti àkọ́kọ́ sí àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.

37 Níkẹyìn, baálé ilé yìí rán ọmọ rẹ̀ pàápàá sí wọn. Ó wí pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ mi.’