35 “Ṣùgbọ́n àwọn olágbàtọ́jú sì mú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọn lu ẹnì kínní, wọn pa èkèjì, wọ́n si sọ ẹ̀kẹ́ta ní òkúta.
36 Lẹ́ẹ̀kejì, ó rán àwọn ìránṣẹ́ tí ó pọ̀ ju ti ìṣaájú sí wọn. Wọ́n sì tún ṣe bí ti àkọ́kọ́ sí àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.
37 Níkẹyìn, baálé ilé yìí rán ọmọ rẹ̀ pàápàá sí wọn. Ó wí pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ mi.’
38 “Ṣùgbọ́n bí àwọn alágbàtọ́jú wọ̀nyí ti rí ọmọ náà lókèèrè, wọ́n wí fún ara wọn pé, ‘Èyí ni àrólé náà. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí a sì jogún rẹ̀.’
39 Wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú ọgbà, wọ́n sì pa á.
40 “Nítorí náà kí ni ẹ ní èrò wí pé olóko náa yóò ṣe pẹ̀lú àwọn alágbàtọ́jú wọ̀nyí nígbà tí ó bá padà dé?”
41 Wọ́n wí pé, “Òun yóò pa àwọn ènìyàn búburú náà run, ní ipò òsì, yóò sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú mìíràn tí yóò fún un ní èso tirẹ̀ lásìkò ìkórè.”