4 Èyí ṣẹlẹ̀ láti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì ṣẹ pé:
5 “Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Síónì pé,‘Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,ní ìrẹ̀lẹ̀, ó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,àti lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’ ”
6 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sí lọ, wọ́n ṣe bí Jésù ti sọ fún wọn
7 Wọ́n sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, wọ́n tẹ́ aṣọ lé e, Jésù si jókòó lórí rẹ̀.
8 Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tẹ́ aṣọ wọn sí ojú ọ̀nà níwájú rẹ̀, ẹlòmíràn sẹ́ ẹ̀ka igi wẹ́wẹ́ wọ́n sì tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà.
9 Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ níwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú ń kígbe pé,“Hòsánà fún ọmọ Dáfídì!”“Olùbùkún ni fún ẹni tí ó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa!”“Hòsánà ní ibi gíga jùlọ!”
10 Bí Jésù sì ti ń wọ Jerúsálémù, gbogbo ìlú mì tìtì, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara wọn pé, “Ta nì yìí?”