9 Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ níwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú ń kígbe pé,“Hòsánà fún ọmọ Dáfídì!”“Olùbùkún ni fún ẹni tí ó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa!”“Hòsánà ní ibi gíga jùlọ!”
10 Bí Jésù sì ti ń wọ Jerúsálémù, gbogbo ìlú mì tìtì, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara wọn pé, “Ta nì yìí?”
11 Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì dáhùn pé, “Èyí ni Jésù, wòlíì náà láti Násárẹ́tì ti Gálílì.”
12 Jésù sì wọ inú tẹ́ḿpì Ọlọ́run. Ó sì lé àwọn ti ń tà àti àwọn ń rà níbẹ̀ jáde. Ó yí tábìlì àwọn onípàsípààrọ̀ owó dànù, àti tábìlì àwọn tí ó ń ta ẹyẹlẹ́.
13 Ó wí fún wọn pé, “A sáà ti kọ ọ́ pé, ‘Ilé àdúrà ni a ó máa pe ilé mi’, ṣùgbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùdó àwọn ọlọ́ṣà.”
14 A sì mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní tẹ̀ḿpìlì, ó sì mú wọ́n láradá
15 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin rí àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá wọ̀nyí, ti wọ́n sì tún ń gbọ́ tí àwọn ọmọdé ń kigbé nínú tẹ́ḿpìlì pé, “Hòsánà fún ọmọ Dáfídì,” inú bí wọn.